Wednesday, 6 April 2016

AWO META

Mo lo ba awon iya osoromoniga,
won fun mi ni eru aye ki n gbe sori,
Irun didi sona meji pelu atupa,
nitori omo meta ni iya aye bi.

Mi o ronu ntori ojukokoro,
ife ti mo ni sowo ju ti emi eniyan,
Ina iro maa n tu lenu mi bi Sango,
o de maa n fele ju iyan.

Ewo aye mi ni meta nnkan,
mi o gbodo jeun lemeta lojumo,
Ti n ba ko owo mi ma tan,
iyen soso ni o je ikilo.

Laimo mo ba awon omo meta iya kana sun,
Eleyi je itan bi aiye mi se gbeyin run.

Adesina Aanuoluwapo Johannu - 2016



No comments:

Post a Comment